ojú- ìwé àkọ́ọ́kàn
Gbígbáradì
ògbufọ̀:

'العربية / Al-ʿarabīyah
Bahasa Indonesia
Català
Deutsch
English
Español
Français
Ελληνικά / Elliniká
Kiswahili
Português
Română
Српски / Srpski
Türkçe
Èdè Yorùbá

                                        

ojú- ìwé mííràn:

àkójọpọ̀-ẹ̀kọ́

olùtọ́sọ́nán ààyè ayélujára

kókó ọ̀rọ̀

Olùbásọ̀rọ̀

Àwọn ìwé tí ó wúlò

Ìsoópọ̀ tí ó wúlò

ẹ̀kọ́ nípa ẹ̀dá ènìyàn àti àsà rẹ̀

Ìtàn kínín

Kò ní Àkọsílẹ̀

nípasẹ̀ Phil Bartle, PhD

Ìtúmọ̀ nípasẹ̀ Tóyìn Jẹ́nyọ̀

Àpèjúwe

Ìtàn kúkúrú láti se àkàwé àgbékalẹ̀ yì í

Kebede jẹ́ Olùsètò tí ó jáfáfá. Àwọn ènìyàn abúlé kan nílò omi tí ó mọ́. Kebede mọ ẹgbẹ́ òkèèrè kan tí kì í se tí Ìjọba tí ó le ràn wọ́n lọ́wọ́ nípa tí owó. Ó sètò ìpàdé pẹ̀lú àwọn asojú abúlé àti ẹgbẹ́ òkèèrè tí kì í se tí Ìjọba yìí Gẹ́gẹ́ bí ó ti tọ́, Kebede kò fi ara rẹ̀ se asojú abúlé.

Àwọn ènìyàn abúlé míràn ńfẹ́ Ilé – ìwé. Kebede sì mọ ẹnìkan ní Ilé - isẹ́ Ìjọba, tí owó tí a yà sọ́tọ̀ fún àwọn ẹgbẹ́ ajìjàgbara tí ó bá fẹ́ kọ́ Ilé – ìwé, wà ní àrọ́wọ́tó rẹ̀. Ara àwọn ènìyàn abúlé yì í bẹ̀rẹ̀ sí í yá gaga nípasẹ̀ Ìjọba agbègbè wọn, wọ́n sì bẹ Kebede láti tọ́ wọn sọ́nà bí wọn yíò se se isẹ́ àgbése abúlé wọn ní àseyọrí. Agbègbè wọn sì kún fún àsàyàn isẹ́ –síse.

Kebede ò gbé àjákọ dání. Kò ní àkosílẹ̀ ohun tí ó ńse àti ìyàtọ̀ tí ó wà ní àarin abúlé méjèèjì. Ó gbàgbé wipe abúlé Hailitown ní omi ẹ̀rọ, nítorínà ó yà wọ̀n ọ́n ní ẹnu láti rí àwọn akọ́sẹ́mọsẹ́ Ìjọba ní abúlé wọn tí wọ́n ńse ìwádìí lórí àìní omi wọn. ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn abúlé New Bede ló jẹ́ Mùsùlùmí, kò sì rọrùn fún wọn láti rí obìnrin pẹ̀lú apá asọ kúkúrú tí ó yọjú láti bàwọn jíròrò lórí àìní Ilé – ìwé wọn. Omi tí ó mọ́ ni wọ́n ńfẹ́. Ní kókó, gbogbo ètò Agbègbè da ojúrú, Ìrẹ̀wẹ̀sì dé bá àwọn ènìyàn, wọn ò tẹ́tí sí Kebede mọ́, ìsekóríyá bá dé òpin.

Àkíyèsí: Àwọn ítàn yìí kì í se àròsọ. A yí orúkọ àwọn ènìyàn àti abúlé padà nítorí ìdánimọ̀.

──»«──
Tí o bá da ọ̀rọ̀ kọ láti orí ààyè ayélujára yìí, jọ̀wọ́ dárúkọ(àwọn) ònkọ̀wé
kí o sì soópọ̀ padà pẹ̀lú cec.vcn.bc.ca/cmp/

© àsẹ 1967, 1987, 2007 Phil Bartle
Ìgbékalẹ̀ ayélujára nípasẹ̀ Lourdes Sada
──»«──
ìmúdójúìwọ̀n ìkẹhìn: 2015.01.08

 ojú- ìwé àkọ́ọ́kàn
Gbígbáradì