Oju Ewe Ibere
 Gbaradi

Awon eda:

'العربية / al-ʿarabīyah
Bahasa Indonesia
বাংলা / Baṅla
Български език
Català
Cebuano / Sugboanon
中文 / Zhōngwén
Deutsch
English
Español
Euskara
Ewe
فارسی / Fārsī
Filipino/Tagalog
Français
Galego
Ελληνικά / Elliniká
ગુજરાતી / Gujarātī
हिन्दी / hindī
Italiano
日本語 / Nihongo
Kiswahili
بهاس ملايو / Bahasa Melayu
Polski
Português
ਪੰਜਾਬੀ / Pañjābī
Română
Русский
Af Soomaali
తెలుగు /Telugu
ไทย / Thai
Tiếng Việt
Türkçe
اردو / Urdu
Èdè Yorùbá

                                        

Awon oju iwe miran

Ipele, Ipele

Aworan ibe

Awon oro ti o se koko

Kan si

Awon iwe ti o wulo

Awon asopo ti o wulo

SE IDAMO AWON AGBEKALE TI O SE KOKO

Awon Agbekale Ati Erongba Ti O Wa Ni Idi Ogbon Amunlo

Lati Owo Ojogbon Phil Bartle, PhD

Ti a Se Eda Re Lati Owo Adebunmi, Amos Adetona


Iwe Idanileko

Awon Agbekale ti olusekoriya gbodo ni oye re

Kin ni idagbasoke? idagbasoke awujo?

Ilowosi ni awujo? Osi? Awujo?

Ifun-ni-lokun? Kiko Akoyawo? Isee se lati gbe duro?

Awon oro yi ni a mun enu ba ni "Awon Koko Oro.")

Lati le je oluse koriya ti o munadoko, o nilo lati mo ju ogbon amulo fun oro siso ni gbangba ati kiko awon eniyan jo fun akitiyan. O nilo lati mon idi ti o fi gbodo se imunlo awon ogbo ise wonyen. O gbodo mo awon agbekale.

Ti o ba se pe awujo kan ni afojusun re, o se pataki ki o mo nipa awon ohun ti o je mo iseda iru awon awujo bee ati oniruru awon ayipada (pelu idagbasoke).

Eyi tumo si pe o nilo imoye lori akojopo awon elegbejegbe, koko oro eko nipa ibagbepo awon eda owo Olorun (sociology), eko nipa awon kokoro (anthropology), eto oro aje, eto oselu, ati awon ipa ati eto ti o je mo elekajeka eko. (Wo "Asa.")

Lowolowo bayi ko tii pondandan fun o lati ni iwe eri akawe gboye lati ile eko giga, sugbon o gbodo ko ara re ni awon agbeale ati oye ni ori awon eko wonyen.

Ti o ba fe lati fun-ni-lokun (fi ipa kun ni) fun awon awujo to oro aje won ko lowo lori pupo, oye iru eni ti ota je gbodo ye o, eyi tii se arun gbi gbe ara le awon eniyan fun iranlowo. (Wo: "Gbidgbe Ara Le Awon Eniyan"). Ti o ba se pe afojusun re ni lati mun osi kuro tabi lati paarun patapata poverty, imo re gbodo ga ju pe a mo awon ohun ti o je apere tabi abayori osi.

O si tun gbodo ni oye nipa awon ohun ti o n se okunfa osi ki o le se iranlowo ki o si gbe ni awon ohun ti a le fi ko oju awon okunfa yen ni aruge.

O gbodo rii pe eto lati se iranlowo fun awon ti osi n se kan le din osi wahala ku fun igba die ni, kii mun osi kuro.

Osi kii kan se oro ti o ni se pelu owo, ati pe owo nikan ko le je ohun elo lati mun osi kuro. (Wo "Awon Agbekale Fun Eto Sise Adinku Fun Osi").

Ti o ba wo "Awon Koko Oro", oo ri ekunrere akosile lori awon koko agbekale fun awon ti o n se ise fun awujo.

O ko le ri itumo ti inu iwe atumo ede (dictionary) fun eyikeyi ninu won; oo ri awon akosile die ti o wulo fun ete iwe yi: ona lati je olusekoriya.

Ipele miran ta ko lehiwa, Awon Agbekale Fun Ifun Awujo Lokun, se ekunrere alaye lori awon agbekale ti o wa lehin awon ona ati ogon ise ti a ni anfani si ni ori ero aye lu ja ara (web site) yi.

Ma se fi awon akosile yen se akosori. Ronu nipa awon agbekale kookan Ko nipa ninu iwe akosile re

Se ifi-ikun-lu- ikun pelu awon akegbe re lori won ni akoko ipade ati idanileko orisirisi. Ni akoko isinmi ranpe, lehin ise pelu awon ore re, fi akoko die sile lati fi ikun lu ikun lori awon agbekale yi, dipo ki a maa soro lori ere boolu ala-fi-ese-gba.

Ati gbiyaju lati ko eko "leekan gbon on" ni a le fi se afiwe pe a n gbiyanju lati jeun "leekan gbon on."

Eko kiko, bii igba ti awujo ba n dagbasoke, ko ye ki o ni opin. Eni ti o ba da owo duro lati maa ko eko ti di oku

––»«––
Ti o ba se adako ohunkohun lati ihin yi, jowo fi oriyin fun eni (tabi awon) ti o koko se agbkale re
ki o si tun pada wa fi ori re so cec.vcn.bc.ca/cmp/

© Ofin adako 1967, 1987, 2007 Phil Bartle
lati owo Lourdes Sada
––»«––
Atunko: 2012.03.18

 Oju Ewe Akoko
Gbigbaradi