Oju Ewe Ibere
 Gbaradi




Awon Eda:

'العربية / al-ʿarabīyah
Bahasa Indonesia
বাংলা / Baṅla
Български език
Català
Cebuano / Sugboanon
中文 / Zhōngwén
Deutsch
English
Español
Euskara
Ewe
Filipino/Tagalog
Français
Galego
Ελληνικά / Elliniká
ગુજરાતી / Gujarātī
हिन्दी / hindī
Italiano
日本語 / Nihongo
Kiswahili
한국어 / hangugeo
بهاس ملايو / Bahasa Melayu
پښتو / Paʂto
Polszczyzna
Português
ਪੰਜਾਬੀ / Pañjābī
Română
Русский
सिन्धी / Sindhi
Af Soomaali
తెలుగు /Telugu
ไทย / Thai
Tiếng Việt
Türkçe
اردو / Urdu
Èdè Yorùbá

                                        

Awon oju iwe miran

Ipele, Ipele

Aworan ibe

Awon oro ti o se koko

Kan si

Awon iwe ti o wulo

Awon asopo ti o wulo

SE IDAMO AWON AFOJUSUN RE

Aseyori wo ni o fe se

Nipase Phil Bartle, Ojogbon

Ti a gbifo re lati owo o Adebunmi Adetona Amos


Iwe Idanileko

Erongba ati afojusun fun jije olusekoriya

Okan ninu awon ede ipolongo ti a n lo fun idanileko awon giwa ni "Nigbati o ko ba mo ibi ti o nlo, ibi gbogbo ni yio da bii oju ona ti o see to."  (Wo "Awon Gbolohun Ipolongo.")

Eyi nii se pelu iwo naa, paapaa, ti o ba ngbaradi fun sise koriya.

O rorun lati ki ara bo opolopo ojuse, ki o si dabi enipe owo kun wa, ki a se eto fun awon ipade, ki a ko ile ilosi, ki a maa ba awon olori ni awujo soro, ki a maa gbe awon oluranlowo ni igbonwo, ki a maa ru awon eniyan soke lati mun ohun kan se, sugbon ti o je pe a ko tesiwaju ninu afojusun wa lati fun awujo ni okun.

O se pataki ki o koko jeki o di mimo, akoko fun ara re, ekeji lori iwe, ati eketa fun awon ti o wa ni ayika re, ohun ti o je afojusun re

Nihin, o gbodo bere si se akosile ninu iwe akosile re, tabi abala ti o ti seto fun akosile awon afojusun ati igbekale re.

O gbodo se igbekale won gege bi afojusun ti ara re gangan, lai maa ronu nipa won bii awon erongba elomiran lasan.

Awon afojusun lati ran awujo lowo le yato laarin enikan si enikeji ati laarin awujo kan si omiran.

Sibesibe, awon ohun ti o baramu wa.

Awon eleyi ni: eto lati fi opin si osi ati ise, eto isejoba ti o dara, ayipada ninu egbe, awujo imun loo rin si fun iseese itesiwaju, fifun awon ti owo oya won kere ati awon ti a ti fi eto won dun won ni okun sii, ati mimu iye okunrin ati obirin se deede

Bi o ti n tesiwaju ninu kika akosile yi, ti o si tun n kopa ninu akitiyan sise koriya, oo se awari pe okookan ninu awon afojusun yi ni o ndun moni ti o si tun peni nija,bi o ti n moo si.

Maa pada loorokore sinu iwe akosile re liti fikun akosile re, ki o tun tun se, ati lati se afikun fun awon afojusun re.

Fun apare, eto lati din osi ati ise ku ma n ta koko o si ma n peninija nigba ti a ba n sise le lori ju igba ti a n se akosile re lo.

A n ko lati yago fun "lile osi ati ise sehin" nitoripe eleyi yio kan din irora ti osi ati ise n mu wa ku ni, kii se ojulowo ona abayo patapata kuro ninu osi ati ise.

Osi ati Ise rekoja oro pe owo ko si lowo, (bi o o se awari nigbaose) ati pe gbigbogun ti orisun osi ati ise tumo si gbigbogun ti ihuwasi ko kan mi, ihuwasi ope, arun, ati etan.

Eyi ni eyokan ninu awon apere bi imoye re nipa afojusun re yio se gbooro sii nipase iriri.

Nibakannaa, eto isejoba ti o dara ko kuku tumo si pe idari ti o se takun-takun ati eto akoso ti o munadoko.

O tun tumosi kiko akoyawo, ilowosi awon eniyan, igbekele, jije olotito ati iran kedere fun ojo iwaju.

Oo ko eko, pelu, pe yio soro lati reti ki awon adari awujo je eniti o nko akoyawo ni ori eto lilo alumoni awujo ti iwo fura ara re ko ba ko akoyawo lori ninu akitiyan re ni awujo.

Wo ni: Akojopo Itumo fun Awon Koko Oro, fun iforo we oro akoko nipa awon afojusun wonyi (eto lati din osi ati ise ku, imutesiwaju awujo).

Fi won we awon akosile ninu iwe akosile re.

––»«––
Ti o ba se adako ohunkohun lati ihin yi, jowo fi oriyin fun eni (tabi awon) ti o koko se agbkale re
ki o si tun pada wa fi ori re so cec.vcn.bc.ca/cmp/

© Ofin adako 1967, 1987, 2007 Phil Bartle
lati owo Lourdes Sada
––»«––
Atunko: 2012.03.18

 Oju Ewe Akoko
Gbigbaradi