ojú- ìwé àkọ́ọ́kàn
Gbígbáradì
ògbufọ̀:

'العربية / Al-ʿarabīyah
Bahasa Indonesia
Català
Deutsch
English
Español
Français
Ελληνικά / Elliniká
Kiswahili
Português
Српски / Srpski
Türkçe
Èdè Yorùbá

                                        

ojú- ìwé mííràn:

àkójọpọ̀-ẹ̀kọ́

olùtọ́sọ́nán ààyè ayélujára

kókó ọ̀rọ̀

Olùbásọ̀rọ̀

Àwọn ìwé tí ó wúlò

Ìsoópọ̀ tí ó wúlò

ẹ̀kọ́ nípa ẹ̀dá ènìyàn àti àsà rẹ̀

Ìtàn kejì

Kò mọ ìlépa rẹ̀

nípasẹ̀ Phil Bartle, PhD

Ìtúmọ̀ nípasẹ̀ Tóyìn Jẹ́nyọ̀

Àpèjúwe

Ìtàn kúkúrú láti se àkàwé àgbékalẹ̀ yì í

Isẹ́ pọ̀ lọ́wọ́ ọ Faith. Ó ní abúlé méje nínú agbègbè tí ó ńse ìríjú fún. Ó sì má a ńgun alùpùpù ẹlẹ́sẹ̀ mẹ́rin rẹ ẹ̀ láti abúlé kan sí èkejì, ìrìnàjò ọlọ́jọ́ gbọọrọ nínú òòrùn.

Alákóso agbègbè sọ wípé “Àwọn ènìyàn yìí kò fẹ́ ètò ẹ̀kọ́, mo fẹ́ kí o mú wọn pinu láti rán àwọn ọmọ wọn lọ sí Ilé – ìwé.”

Nìwọ̀n ìgbà tí Faith ti ma ńlọ láti abúlé sí abúlé, ó kuku ńgba àwọn ènìyàn ní ìyànjú láti rán àwọn ọmọ lọ sí Ilé- ìwé nínú ìdánilẹkọọ rẹ̀.

Olùsọ́-àgùntàn Faith sọ wípé “Àwọn ènìyàn yìí sì ńsin èṣù, Mo fẹ́ kí wọ́n má a wá sí Ilé- Ijọ́sìn.”

Nítorí ìdí èyí, ó tún ńgba àwọn ènìyàn ní ìyànjú láti má a lọ sí Ilé- Ijọ́sìn nínú ìdánilẹkọọ rẹ̀. Olùtọ́jú aláìsàn ti agbègbè náà tún sọ wipe “Àwọn ènìyàn yìí kò se ìmọ́tótó tí ó péye. Ó tún bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ lórí i ọwọ́ fífọ̀ àti lílo Ilé- ìgbànsẹ̀ dáradára nínú ìdánilẹkọọ rẹ̀. Báyìí ni ó se ńba lọ, tí ó fi jẹ́ pé nígbàkúgbà tí òsìsẹ́ ìjọba míràn bá dábàá pé kí àwọn ará abúlé se tibí tàbí tọ̀hún, Faith má a ńfi wọ́n kún ìdánilẹkọọ rẹ̀ ni. Ní ìgbà tí ó fi má a di òpin ọdún, kòsí ohun èlò àwùjọ kan tí wọ́n kọ́ tàbí túnse.

Faith sọ wípé “ Kí ló dé"

Díẹ̀ lára àwọn ará abúlé dáhùn pé “ A ńtẹ́ etí sí ọ ní gbogbo ìgbà tí o bá wá sí abúlé wa, sùgbọ́n ọ́ dà bí eni wípé o kò í tí ì bẹ̀rẹ̀ sí ràn wá lọ́wọ́ láti se ohun tí a fẹ́

Àkíyèsí: Àwọn ítàn yìí kì í se àròsọ. A yí orúkọ àwọn ènìyàn àti abúlé padà nítorí ìdánimọ̀.

──»«──
──»«──
Tí o bá da ọ̀rọ̀ kọ láti orí ààyè ayélujára yìí, jọ̀wọ́ dárúkọ(àwọn) ònkọ̀wé
kí o sì soópọ̀ padà pẹ̀lú cec.vcn.bc.ca/cmp/

© àsẹ 1967, 1987, 2007 Phil Bartle
Ìgbékalẹ̀ ayélujára nípasẹ̀ Lourdes Sada
──»«──
ìmúdójúìwọ̀n ìkẹhìn: 2015.01.08

 ojú- ìwé àkọ́ọ́kàn
Gbígbáradì