ojú- ìwé àkọ́ọ́kàn
Gbígbáradì


ògbufọ̀:

                                        

ọ̀nà kíkà mííràn:

Ìpamọ́ ọ̀rọ̀
Ìgbékalẹ̀ ayára bí Àsá

ojú- ìwé mííràn:

àkójọpọ̀-ẹ̀kọ́

olùtọ́sọ́nán ààyè ayélujára

kókó ọ̀rọ̀

Olùbásọ̀rọ̀

Àwọn ìwé tí ó wúlò

Ìsoópọ̀ tí ó wúlò

ÌGBÁRADÌ FÚN ÀWỌN OLÙSEKÓRÍYÁ

Ìtọ́sọ́nà fún àwọn Olùkọ́ni

nípasẹ̀ Phil Bartle, PhD

Ìtúmọ̀ nípasẹ̀ Tóyìn Jẹ́nyọ̀


Àkọsílẹ̀ Olùkọ́ni

Lílo àkójọpọ̀-ẹ̀kọ́ yí fún Ìkọ́ni

Tani Ó Leè Di Ajìjàgbara Àwùjọ?

Gbogbo ènìyàn kọ́ ni ó ní àbùdá Olùsekóríyá Àwùjọ.

Má se lérò wipe, kíkọ́ ẹ̀kọ́ gboyè nìkan le è sọ ènìyàn di òsìsẹ́ àwùjọ. Ní pàtó, níní ìwé - ẹ̀rí kan tàbí òmíràn ní orí Isẹ́ - Àwùjọ tàbí àwọn ẹ̀kọ́ míràn tí ó jẹmọ́ ọ, kò ní kí ènìyàn jáfáfá láti ran àwùjọ àwọn aláìní lọ́wọ́. Àwọn Onímọẹ́rọ, akẹ̀kọ́gboyè nínú ètò ọrọ̀ọ̀ajé tàbí ìmọ̀ ìjìnlẹ̀, pàápàá jùlọ àwọn ènìyàn tí kò lò ju ọdún kan lọ ní ilé-ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ti se àseyọrí ninu isẹ́ àwùjọ.

Níwọ̀n bí ó bá ti seése, jíjẹ́ òsìsẹ́ àwùjọ ní láti ti ọkàn wà

Tí a bá fẹ́ kọ́ àwọn tí ó ní ipá láti di olùsekóríyá, ètò ìkọ́ni wa ní láti fún àwọn akẹ́ẹ̀kọ́ wa ní ànfàní láti yan ọ̀nà tí ó wù wọ́n pẹ̀lú ìrọ̀rùn

Àwọn èròjà inú Àkójọpọ̀-ẹ̀kọ́ ní orí ìgbáradì yí ni a leè lò láti fi hàn àwọn tí ó ní ipá láti di olùsekóríyá bí ìsẹ̀dá isẹ́ wọn se rí, irú àbùdá ti ara ẹni tí wọ́n nílò, àti irú ẹ̀kọ́ wo ni wọ́n o là kọjá. Lo èyí láti fún wọn ní ànfàní láti pinnu bóyá wọn ó ò tẹ̀síwájú nínú ẹ̀kọ́ wọ́n

:Àwọn èròjà ìdánilẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀

Àkójọpọ̀-ẹ̀kọ́ máàrún àkọ́kọ́ lórí ààyè ayélujára, nínu ìdánilẹ̀kọ́ yì í ní ìwé-ìlànà kékeré, tí ó wúlò fún ìdánilẹ̀kọ́ onífiọ̀rọ̀wéọ̀rọ̀, tí a ní láti jíròrò lé lórí, láti tò ó lẹ́sẹsẹ àti ní ìpele ní ìpele. Wọ́n dá lórí àkóónu ìwé-ìlànà àkọ́kọ́, tí a ti gbékalẹ̀ ní odidi ní abala míràn lórí ààyè ayélujára yì í. (Ìwé-ìlànà Olùsekóríyá). A pín wọn sí ìwé-ìlànà kékèké níbíyí láti le è lò ó ní ọ̀tọ̀tọ̀ fún ìjíròrò ìdánilẹ̀kọ́ onífiọ̀rọ̀wéọ̀rọ̀.

O lè gba àwọn akẹ́kọ́ gíga ní ìmọ̀ràn láti wo ìwé-ìlànà tí wọ́n bá fẹ́ ka ìwé tí ó pọ̀, tí ó ní gbogbo àwọn èròjà ní ojúkan.

Àwọn Àkójọpọ̀ ẹ̀kọ́ tí a ó wà ní iwájú ní ìwé tí ó pọ̀ pẹ̀lú àkóónú tí ó nípọn

Ìwé-ìlànà kọ̀ọ̀kan ni a lè lò fún ẹ̀kọ́ ogójì ìsẹ́jú ( lílo orúkọ kańnà fún àsìkò ẹ̀kọ́ kọ̀ọ̀kan) nínu ìdánilẹ̀kọ́ ìbẹ̀rẹ̀. O sì le è lo àwọn àkòrí ní ìgbàtí o bá palẹ̀mọ́ fún ẹ̀kọ́ rẹ.

Bíbẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo àkójọ ní orí olùtọ́sọ́nán ààyè ayélujára, o le è to àwọn ẹ̀kọ́ rẹ gẹ́gẹ́bí wọ́n se ńfarahàn nínu àkójọpọ̀ ẹ̀kọ́ máàrún àkọ́kọ́, tàbí kí o tun wọn tò gẹ́gẹ́bí ìwọ áti àwọn akẹ́kọ́ se nílò wọn.

O sì le è se ẹ̀dà Ìwé-ìlànà kọ̀ọ̀kan, tàbí kí o yan ní ara wọn sí orí ẹ̀rọ tí ó nfẹ ìran láti le è fi àyè gba ìgbékalẹ̀, ìjíròrò áti ìkópa. Ó kù sí ẹ lọ́wọ́ bí o se bá fẹ́ lo èròjà rẹ

Ó dára kí àsìkò ìdánilẹ̀kọ́ kọ̀ọ̀kan kún fún ọ̀nà ”Ìkópa“ fún àwọn akẹ́kọ́, pẹ̀lú ìwọ̀nba kíkọ́ àti ìgbékalẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Olùdarí. O le è ronú àwọn ọ̀nà míràn tí ó le jẹ́ kí àwọn akẹ́kọ́ kó ipa tí ó ní àpẹrẹ ní àsìkò ìdánilẹ̀kọ́ kọ̀ọ̀kan, ó sì ma wúlò tí o bá se ìwé àkópọ̀ fún wọn tí a ó ò le ma lò ní àsìkò ìdánilẹ̀kọ́ síwájú sii.

Kíni ó ńsisẹ́ fún ẹ, àti báwo ni ó se ńsisẹ́?

Àwọn ìwé tí ó fi ara pẹ́ ẹ̀kọ́ yí nínú àwọn àkójọpọ̀ ẹ̀kọ́ míràn:

Àwọn ìwé méjì tí ó wà nínú àwọn àkójọpọ̀ ẹ̀kọ́ míràn le è wúlò tí ó bá fẹ́ fi kún àwọn tí ó wà nínú àkójọpọ̀ ẹ̀kọ́ yì í

Nínú àkójọpọ̀ ẹ̀kọ́ "Agbo ìsekóríyá" àwọn ìwé lórí "Jíjẹ́ Olùsekóríyá “ le è wúlò gidigidi ní ibíyì. A le è pin si Ìwé-ìlànà méjì, ọ̀kan ní àkójọ àwọn àbùdá ti ara ẹni tí a nílò, kí àwọn akẹ́ẹ̀kọ́ le è ri gẹ́gẹ́bí àkọsílẹ̀ tí wọn yí ò fi wò ó tí wọn bá ní irú àwọn àbùdá bẹ́ẹ̀, Èkejì má a jẹ́ àkọsílẹ̀ tí ó rọrùn lórí isẹ́ tí ó yẹ kí olùsekóríyá se ní ẹnu isẹ́. ọ̀kan tàbí Ìwé-ìlànà méjèèjì ni a le è lò ní abala “ìgbáradì” yì í.

Nínú "Sísàkóso Ìsekóríyá“Àkójọpọ̀-ẹ̀kọ́, àwọn ìwé-ìpamọ́”Ìsàpèjúwe isẹ́“ pèsè Ìsàpèjúwe pẹ̀lú àlàyé lórí ìwé-ẹ̀rí tí a nílò áti àwọn isẹ́ áti ojúse tí a ńretí.

Àkójọpọ̀-ẹ̀kọ́ yẹn áti “Ìsàkóso Ìkópa“ méjèèjì dábàá wípé ìbásepọ̀ láàrín olùsàkóso áti olùsekóríyá ní láti jẹ́ alábàásepọ̀, wọ́n ní láti se isẹ́ papọ̀ láti gbé Ìsàpèjúwe isẹ́ olùsekóríyá jáde . ( Ó se ni láànú pé gbogbo àwọn olùsekóríyá kọ́ ni yíò bá ara rẹ̀ lábẹ́ olùbójútó mú ìsàkóso ìkópa sí ojúse - àwọn àkójọpọ̀-ẹ̀kọ́ méjèèjì yẹn ni ó gbelárugẹ ).

Tí akẹ́ẹ̀kọ́ bá béèrè àlàyé tí ó ju ohun tí ó wà nínú àwọn Ìwé-ìlànà ti “Gbígbáradì” nígbà náà ni Ìwé-ìlànà Ìsàpèjúwe isẹ́ ma wúlò

àwọn ọ̀nà ìkọ́ni :

Odidi àkójọpọ̀ ẹ̀kọ́ lórí ààyè ayélujára ni a yà sọ́tọ̀ fún ìgbékalẹ̀ orísirísi ọ̀nà ìkọ́ni tí o le è fọwọ́bà ní ìgbà tí o bá ńlo èròjà yì í fún ìkọ́ni.(àwọn ọ̀nà ìkọ́ni)

Ní ìgbà tí o bá ńse ètò fún ìbẹ̀rẹ̀ ìdánilẹ̀kọ́ onífiọ̀rọ̀wéọ̀rọ̀ lórí àkòrí “Gbígbáradì,” wá inú àkójọpọ̀-ẹ̀kọ́ ” àwọn ọ̀nà ìkọ́ni" fún ìdarí áti ìtalólobó lórí bí o se le è se gbé ètò ìkọ́ni rẹ kalẹ̀

Jákèjádò ààyè ayélujára yìí àti àwọn ètò ìkọ́ni inú rẹ̀, àtẹnumọ́ wà lórí “ìkẹ́ẹ̀kọ́ nípa Ìkópaọ̀nà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni gbogbo wa ńfi ńkẹ́ẹ̀kọ́, láti orí bí a se yára sí títí dé ohun tí a fi ńkẹ́ẹ̀kọ́. Ní gbogboogbò, a ó ò kẹ́ẹ̀kọ́ ní àkọ́yé pàápàá jùlọ ní olóríjorí pẹ̀lú Ìkópa ju gbígbọ́ tàbí wíwò nìkan lọ.

A gbà ọ́ níyànjú láti máse fojú sí ọ̀nà ìkọ́ni bí i àtẹ̀hìnwá, lo ojú inú àti àtinúdá rẹ láti gbé ètò ìkọ́ni rẹ kalẹ̀ gẹ́gẹ́bí àìní àti ipò àwọn akẹ́ẹ̀kọ́ àti agbègbè ìkẹ́ẹ̀kọ́.

Tí o bá ńse ètò ìkọ́ni lọ́wọ́lọ́wọ́, a gbà ọ́ níyànjú láti kọ ìwé sí wa láti báwa jíròrò lórí àkíyèsí àti èrò rẹ. Tí o bá ní àbá, ó sese kí a jùmọ̀ sètò èròjà titun.

──»«──
Tí o bá da ọ̀rọ̀ kọ láti orí ààyè ayélujára yìí, jọ̀wọ́ dárúkọ (àwọn) ònkọ̀wé
kí o sì soópọ̀ padà pẹ̀lú www.scn.org/cmp/

© àsẹ 1967, 1987, 2007 Phil Bartle
Ìgbékalẹ̀ ayélujára nípasẹ̀ Lourdes Sada
––»«––
ìmúdójúìwọ̀n ìkẹhìn: 2014.11.04

 ojú- ìwé àkọ́ọ́kàn

 Gbígbáradì